Hymn 699 – ILẸ kan mbe to dara julo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ILẸ kan mbe to dara julo" (C&S Hymn #699, Yoruba). ILẸ kan mbẹ to dara julọ, A le fi 'gbagbọ ri l'okere, Nitori Baba…
ILẸ kan mbẹ to dara julọ, A le fi 'gbagbọ ri l'okere, Nitori Baba duro l'ọna, Lati fi'le kan fun wa nibẹ. Kérúbù, Séráfù, ) Ẹ ho fun ayọ lọjọ oni. )2ce Awa y'o kọrin l'ebute na, Orin didun awọn t'a bukun, Ọkan wa ko ni banujẹ mọ, 'Tori ayọ ailopin wa n'bẹ. Kérúbù, Séráfù, ) Ẹ ho fun ayọ lọjọ oni. )2ce Baba wa olore ni ọrun, Nikan n'iyin at'ọpẹ yẹ fun; 'Tori ẹbun ogo ifẹ Rẹ, Eyi ti se Olugbala wa. Kérúbù, Séráfù, ) Ẹ ho fun ayọ lọjọ oni. )2ce Tan 'mọlẹ Rẹ si okunkun wa, L'akoko t'ẹgbẹ Séráfù de; Ki gbogbo ayé le yipada, Lati juba fun Krisit Oluwa. Kérúbù, Séráfù, ) Ẹ ho fun ayọ lọjọ oni. )2ce 'Gba t'a gbe agọ erupẹ wọ, Ti ọta ba fẹ se wa n'ibi, T'erokero ba fẹ gb'ọkan wa, Ki Jehofa ko gbọ ẹbẹ wa. Kérúbù, Séráfù, ) Ẹ ho fun ayọ lọjọ oni. )2ce Nigba t'o ba d'ọjọ ikẹhin, Ti ọmọ ko ni mọ baba rẹ; Ma jẹ k'oju ti wa lọjọ na, Ki Mẹtalọkan tẹwọ gba wa. Kérúbù, Séráfù, ) Ẹ ho fun ayọ lọjọ oni. )2ce AMIN Kérúbù, Séráfù, ) Ẹ ho fun ayọ lọjọ oni. )2ce
Hymn 699 – ILẸ kan mbe to dara julo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia