Hymn 697 – NIHIN l'Oruko Re Oluwa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "NIHIN l'Oruko Re Oluwa" (C&S Hymn #697, Yoruba). NIHIN l'Orukọ Rẹ Oluwa, A kọ ile 'rupẹ yi fun Ọ, Yan fun 'bugbe Rẹ…

Hymn 697 – NIHIN l'Oruko Re Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
NIHIN l'Orukọ Rẹ Oluwa, A kọ ile 'rupẹ yi fun Ọ, Yan fun 'bugbe Rẹ Pataki, K'o si sọ lọwọ 'ja esu. Gba t'a ba n gbadura nihin, T'ẹlẹsẹ n bẹbẹ fun IYE, Gbọ lati 'bugbe Rẹ Ọrun, Gba t'o ba gbọ k'o dariji. Gba t'a n wasu Rẹ nihin, Ninu Ile Mimọ Rẹ yi, Nip' agbara Oke nla Rẹ, K'isẹ 'yanu Rẹ farahan. Gba t'awọn ewe ba n kọrin, Hosanna si Ọba wa loke, Ki ogo Rẹ kun ile yi, K'Angeli ba wọn kọrin na. K'ogo Rẹ ma gbe ile yi, Yan ni ile patapata, Tẹ itẹ Rẹ sinu 'le yi, Ma jẹ ki esu le wo bẹ. Jah Jehofa, Ọba Mimọ, Sọkalẹ sinu ọkan wa, Ma ba wa gbe inu ile wa, Mase fi wa silẹ lailai. AMIN

Hymn 697 – NIHIN l'Oruko Re Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia