Hymn 694 – JEJE laisi ariwo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JEJE laisi ariwo" (C&S Hymn #694, Yoruba). JẸJẸ laisi ariwo, Jẹjẹ sa ni orun n ran, Gba t'o ba yọ ni ila rẹ, Ẹda si le…
JẸJẸ laisi ariwo, Jẹjẹ sa ni orun n ran, Gba t'o ba yọ ni ila rẹ, Ẹda si le wo oju rẹ, B'o si ti n goke pẹlẹ, Jẹjẹ l'agbara rẹ n pọ, Titi y'o fi kan 'tari, Nin' ogo t'a ko le wo. Okunkun t'o n'ipa ju, Ko wa pẹlu okiki, Osupa ati Irawọ, Ti n tan 'mọlẹ y'ayé ka, Wọn ko wa pẹlu iro, Iri nla ti o n sẹ, Yi gbogbo ayé yi ka, Ko wa pẹlu okiki. Bayi n'isẹ ỌLỌRUN, Larin ẸGBẸ MIMỌ yi, B'a ti jẹ alailera, T'agbara wa ko si pọ, Sugbọn ipese BABA , 'Jojumo l'o n yọ si wa; Nipa 'GBARA ỌLỌRUN A kọ ile na pari. Loni yi, ỌLỌRUN wa, Awa Ẹgbẹ Séráfù, Ọmọde ati agba, Ọkunrin at'Obinrin, Onile at' alejo, T'o wa fi ọpẹ fun Ọ, Ninu ile Mimọ yi, Masai tẹwọ gb'ọpẹ wa. ỌLỌRUN MẸTALỌKAN, T'o da Ẹgbẹ yi silẹ, Ya ile yi si MIMỌ, Nipa AGBARA nla Rẹ, Sọkalẹ l'ọjọ oni, F'agbara wọ gbogbo wa, Ki gbogbo wa jẹ TIRẸ, Layé yi ati l'ọrun. AMIN
Hymn 694 – JEJE laisi ariwo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia