Hymn 695 – EYIN ara n'n' Oluwa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EYIN ara n'n' Oluwa" (C&S Hymn #695, Yoruba). ẸYIN ara n'n' Oluwa, T'ẹ wa a ba wa pejọ, Fun ajọdun (Isọji Isile) Lati…

Hymn 695 – EYIN ara n'n' Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
ẸYIN ara n'n' Oluwa, T'ẹ wa a ba wa pejọ, Fun ajọdun (Isọji Isile) Lati 'lu gbogbo wa, A ki yin Ẹ ku 'yedun, K'Oluwa pẹlu yin, K'ỌLỌRUN OLODUMARE, Fi 'bukun sọri yin. Ẹ ho, ẹ yọ, ẹ gberin, Kérúbù Séráfù, BABA wa yoo gb'owo wa, A ko ni padanu. A ki awọn Alaga, Ninu ẹgbẹ gbogbo, Awọn ọkunrin, At'awọn obinrin, Bẹni awọn ariran, Ti n se amọna wa, Ki BABA din yin l'amure, Ododo Rẹ d'opin. Ẹ ho, ẹ yọ, ẹ gberin, Kérúbù Séráfù, BABA wa yoo gb'owo wa, A ko ni padanu. Gbogb' ẹgbẹ Aladura, At'ẹgbẹ Bibeli, Ẹyin ẹgbẹ, Akọrin, Pẹlu gbogb' ọm' ẹgbẹ; Gbogbo ẹyin t'ẹ yagan, At' alairisẹ se, JEHOVAH JIRE yoo pese, Fun aini yin gbogbo. Ẹ ho, ẹ yọ, ẹ gberin, Kérúbù Séráfù, BABA wa yoo gb'owo wa, A ko ni padanu. Ara ẹ jẹ k'a ranti, Awọn t'o sako lọ, Jesu jọ mu wọn pada, Gbin wọn si agbo Rẹ, Wo gbogb' awọn alaisan, Fun wọn ni ilera, Jẹ ki awọn t'o ti kọja, Ri gbal'ọkan wọn he. Ẹ ho, ẹ yọ, ẹ gberin, Kérúbù Séráfù, BABA wa yoo gb'owo wa, A ko ni padanu. Gbogbo ẹyin alejo, T'ẹ n fi wa silẹ lọ, Abo OLODUMARE, Yoo ma ba yin lọ, Awọn Angẹli mimọ, Yoo rọgba yi yin ka, JESU OLUWA yoo sọ yin, De 'le l'alafia. Ẹ ho, ẹ yọ, ẹ gberin, Kérúbù Séráfù, BABA wa yoo gb'owo wa, A ko ni padanu. O digbose ara wa, Oju ro wa pupọ; Sugbọn a ki o banujẹ, B'ẹni ko ni 'reti, B'ara wa jinna s'ara, K'emi wa wa lọkan; K' ibukun OLODUMARE, Ma ba wa gbe titi. Ẹ ho, ẹ yọ, ẹ gberin, Kérúbù Séráfù, BABA wa yoo gb'owo wa, A ko ni padanu. Njẹ 'gba t'a ba si pe wa, Lati f'ayé silẹ, K'Angel' gbe wa s'ọrun, S'okan aya BABA; Nibẹ k'a ba JESU gbe, Larin ẹgbẹ Mimọ, K'OGO, ỌLA at'AGBARA, Jẹ tirẹ ỌLỌRUN, Ẹ ho, ẹ yọ, ẹ gberin, Kérúbù Séráfù, BABA wa yoo gb'owo wa, A ko ni padanu. AMIN Ẹ ho, ẹ yọ, ẹ gberin, Kérúbù Séráfù, BABA wa yoo gb'owo wa, A ko ni padanu.

Hymn 695 – EYIN ara n'n' Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia