Hymn 693 – A FI ipile yi le'le | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "A FI ipile yi le'le" (C&S Hymn #693, Yoruba). A FI ipilẹ yi le'lẹ Ni orukọ Rẹ Oluwa, Awa mbẹ Ọ, Oluwa wa wa, Ma tọju…

Hymn 693 – A FI ipile yi le'le | C&S Yoruba Hymnary
A FI ipilẹ yi le'lẹ Ni orukọ Rẹ Oluwa, Awa mbẹ Ọ, Oluwa wa wa, Ma tọju ibi mimọ yi. 'Gba t‗eniyan Rẹ ba n wa Ọ, T'ẹlẹsẹ n wa Ọ n'ile yi, Gbọ, Ọlọrun, lat'ọrun wa, F'ẹsẹ wọn ji wọn Ọlọrun. 'Gba awọn Alufa ba n wasu, Ihinrere ti Ọmọ Rẹ; Ni orukọ Rẹ, Oluwa, Ma sisẹ iyanu nla Rẹ. 'Gb' awọn ọmọde ba si n kọ, Hosannah si Ọba wọn, Ki Angẹli ba wọn kọ pẹlu, K'ọrun at'ayé jọ gberin. Jehovah, o ha ba ni gbe, Ni ayé buburu wa yi? Jesu, o ha jẹ Ọba wa, Emi o ha sinmi nihin? Ma jẹ ki ogo Rẹ kuro, Ninu ile ti a n kọ yi; Se 'jọba Rẹ ni ọkan wa, Si tẹ itẹ Rẹ sinu wa. AMIN

Hymn 693 – A FI ipile yi le'le | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia