Hymn 690 – E GB'ORO Oluwa l'enu 'ranse Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E GB'ORO Oluwa l'enu 'ranse Re" (C&S Hymn #690, Yoruba). Ẹ GB'ỌRỌ Oluwa l'ẹnu 'ransẹ Rẹ, Gbọ 'bukun Oluwa fun…
Ẹ GB'ỌRỌ Oluwa l'ẹnu 'ransẹ Rẹ, Gbọ 'bukun Oluwa fun Serubabeli, Ọwọ Serubabeli lo bẹrẹ 'le yi Oun na ni y'o si kọ d'opin. A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun, A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun. Ẹ gb'ọrọ Oluwa l'ẹnu 'ransẹ Rẹ, B'o ti wu mi lati pọn yin loju ri, Bẹni Emi yoo si se yin l'ogo, Ayé yoo ri, y'o yin mi l'ogo. A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun, A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun. A Sioni ma p'ohunrere ẹkun mọ, Igba awẹ rẹ ti de opin rẹ na; Awọn ọmọkunrin ni igboro rẹ, L'Emi yoo fi se ọ l'ogo. A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun, A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun. Wura ati fadaka ki y'o wọn ọ, Ogo Mi y'o si ma gbe ni arin rẹ, A o bukun f'oril' ede nipa rẹ, 'Wọ sa gbẹkẹle Ọlọrun rẹ. A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun, A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun. Se Emi ni Alfa ati OMEGA, Se Emi na l'o da Ọrun at'ayé, Emi ki yoo sa fi ọ silẹ dandan, Emi l'Ọba Awimayẹhun, A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun, A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun. Bi mo ti wa ki a to da ayé yi, Bẹni mo wa titi di isinsin yi, Emi l'Ẹni t'o se Solomon l'Ogo, Emi yoo se yin l'Ogo dandan. A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun, A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun. L'orukọ Ọwọ Mi ni mo se 'leri, Oruko Ogo Mi ni Majẹmu yin, Ẹ ki y'o pe MI ni alairi 'dahun B'ọrun at'ayé rekọja lọ. A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun, A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun. AMIN A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun, A! ẹ ku ayọ, Jesu ti se 'leri 'bukun.
Hymn 690 – E GB'ORO Oluwa l'enu 'ranse Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia