Hymn 689 – IPILE ti Jesu fi le'le l'eyi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IPILE ti Jesu fi le'le l'eyi" (C&S Hymn #689, Yoruba). IPILẸ ti Jesu fi le'lẹ l'eyi Ti Baba Aladura n tọ, K'ẹda mase…

Hymn 689 – IPILE ti Jesu fi le'le l'eyi | C&S Yoruba Hymnary
IPILẸ ti Jesu fi le'lẹ l'eyi Ti Baba Aladura n tọ, K'ẹda mase ro pe, O yẹ kuro nibẹ, o duro le Krist' apata. Kérúbù ẹ yọ, Séráfù ẹ yọ, A fi 'pilẹ lelẹ lori otitọ (2) Bi ara n san ẹgbagbeje ohun, Ọmọ Jesu yoo duro ti, K'eniyan ma kẹgan ọkọ Noa, Oko refo ọmọ Jesu la. Kérúbù ẹ yọ, Séráfù ẹ yọ, A fi 'pilẹ lelẹ lori otitọ (2) A ro‘jọ mọ Stephen, a ro'jọ mọ Peter, A ro‘jọ mọ Jesu Oluwa, A ro‘jọ mọ Mose Orimọlade, K'ẹda k'o kiyes' ara. Kérúbù ẹ yọ, Séráfù ẹ yọ, A fi 'pilẹ lelẹ lori otitọ (2) Baba Aladura dide damure, Lati pade awọn Kérúbù, Ọlọrun ti yin isẹ Rẹ lat'oke wa, Ade iye yoo jẹ tirẹ. Kérúbù ẹ yọ, Séráfù ẹ yọ, A fi 'pilẹ lelẹ lori otitọ (2) B'ayé mbu Mose, awọn Angeli n fẹ, Ọlọrun Abraham n fẹ, Awọn Ogun Ọrun si n gbadura rẹ, Ọlọrun Mẹtalọkan. Kérúbù ẹ yọ, Séráfù ẹ yọ, A f' ipilẹ lelẹ lori otitọ (2) AMIN Kérúbù ẹ yọ, Séráfù ẹ yọ, A f' ipilẹ lelẹ lori otitọ (2)

Hymn 689 – IPILE ti Jesu fi le'le l'eyi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia