Hymn 688 – WO awon apere wonni | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WO awon apere wonni" (C&S Hymn #688, Yoruba). WO awọn apẹrẹ wọnni, Ti mbẹ n'nu Bibeli, T'awọn t'o fẹ Isin Jesu, Lati…

Hymn 688 – WO awon apere wonni | C&S Yoruba Hymnary
WO awọn apẹrẹ wọnni, Ti mbẹ n'nu Bibeli, T'awọn t'o fẹ Isin Jesu, Lati 'gba ewe wọn. Jesu, Ọba l'oke ọrun, T'ọla Rẹ kun ayé, Jẹ ọmọde bi emi ri, O n p'ofin Baba mọ. Mejila pere l'ọdun Rẹ; 'Gb'o n damu awọn Ju; Sugbọn sibẹ, o tẹriba, O si gbọ t'iya Rẹ. B'awọn agba ti n kẹgan to, Ti wọn n s'abuku Rẹ, Bẹ l'awọn ewe yin logo, Ti wọn n ke Hosanna! Bi Samueli, Timoti, Lat' igba ewe wọn; Ti n f'itara sin Oluwa, Bẹ l'o yẹ ki n ma se. Ko tọ ki n f'isin Oluwa, Se 'jafara rara; Ki y'o di ọla ki n to bẹrẹ, Si isẹ rere yi. AMIN

Hymn 688 – WO awon apere wonni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia