Hymn 691 – KRISTI n'ipile wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KRISTI n'ipile wa" (C&S Hymn #691, Yoruba). KRISTI n'ipilẹ wa, Lori Rẹ la o kọle; Awọn Mimọ nikan, L'o n gb'agbala…
KRISTI n'ipilẹ wa, Lori Rẹ la o kọle; Awọn Mimọ nikan, L'o n gb'agbala ọrun. Ireti wa, T'ore ayé, T'ayọ ti mbọ Wa n'nu 'fẹ Rẹ. Agbala Mimọ yi, Y'o ho f'orin iyin, A o kọrin iyin si, Mẹtalọkan Mimọ, Bẹ la o f'orin, Ayọ kede, Orukọ Rẹ, Titi ayé. Ọlọrun Olore, Fiye si ni, nihin; Lati gba ẹjẹ wa, At'ẹbẹ wa gbogbo K'o si f'ọpọ, Bukun dahun, Adura wa, Nigba gbogbo Nihin, jẹ k'ore Rẹ, T'a n tọrọ l'at'ọrun, Bọ sori wa lẹkan, K'o ma si tun lọ mọ, di Tit'ọjọ na, T'a o s'akojọ, Awọn Mimọ, Sib' isinmi. AMIN
Hymn 691 – KRISTI n'ipile wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia