Hymn 681 – ORUKO wo lo dun gbo bi t'iya | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ORUKO wo lo dun gbo bi t'iya" (C&S Hymn #681, Yoruba). ORUKỌ wo lo dun gbọ bi t'iya, Ti eti n gbọ ti ọkan si balẹ;…

Hymn 681 – ORUKO wo lo dun gbo bi t'iya | C&S Yoruba Hymnary
ORUKỌ wo lo dun gbọ bi t'iya, Ti eti n gbọ ti ọkan si balẹ; Adun t'ẹnu ko le sọ miran wo, Ninu orukọ rere bi t'iya. A! iya ti n gba 'ya ọmọ rẹ jẹ A! iya ti n gbẹkun ọmọ rẹ sun, A! iya ti n pebi mọnu f'ọmọ Mo fẹ ọ nigba gbogbo iya ọwọn. Jọwọ ran mi lọwọ, Edumare K'emi le tọju awọn obi mi, Fun mi layọ pupọ nigb' ayé mi, Ki n ma sanku mọ obi mi loju. Agbọrandun bi iya ko si, Ẹni to ni baba lo tara rẹ; Bi ina ku a fi eru boju, Iya mi ti fi mi rọpo 'ra rẹ. AMIN

Hymn 681 – ORUKO wo lo dun gbo bi t'iya | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia