Hymn 680 – MASE huwa ese | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MASE huwa ese" (C&S Hymn #680, Yoruba). MASE huwa ẹsẹ, Ma sọrọ 'binu, Ọmọ Jesu l'ẹ n se, Ọmọ Oluwa. Krist jẹ oninure,…

Hymn 680 – MASE huwa ese | C&S Yoruba Hymnary
MASE huwa ẹsẹ, Ma sọrọ 'binu, Ọmọ Jesu l'ẹ n se, Ọmọ Oluwa. Krist jẹ oninure, At'Ẹni mimọ; Bẹ l'awọn ọmọ Rẹ, Yẹ k'o jẹ mimọ. Ẹmi ibi kan wa, T'o n sọ irin rẹ; O si n fẹ dan ọ wo, Lati se ibi. Ẹ mase gbọ tirẹ, B'o tilẹ sọrọ; Lati ba Esu ja, Lati se rere. Ẹyin ti se'leri, Ni ọmọ ọwọ, Lati k'Esu silẹ, Ati ona rẹ. Om'ogun Krist ni yin, Ẹ kọ lati ba, Ẹsẹ inu yin ja; Ẹ ma se rere. Jesu l'Oluwa yin, O se ẹni 're, Ki ẹyin ọmọ Rẹ, Si ma se rere. AMIN

Hymn 680 – MASE huwa ese | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia