Hymn 679 – K'IYA wa, Efa, to d'ese | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "K'IYA wa, Efa, to d'ese" (C&S Hymn #679, Yoruba). K'IYA wa, Efa, to d'ẹsẹ, Tal'o mọ ohun ti njẹ asọ? Ohun t'a fi bo…

Hymn 679 – K'IYA wa, Efa, to d'ese | C&S Yoruba Hymnary
K'IYA wa, Efa, to d'ẹsẹ, Tal'o mọ ohun ti njẹ asọ? Ohun t'a fi bo l'asiri, Pada d'ohun irira rẹ. 'Gba t'o ko gb'ewe ọpọtọ wọ, Ọsọ ―iwa mimọ‖ rẹ lọ! Sa wo bi awa ọmọ rẹ Ti n f'i bo 'tiju yi sogo. Wo! b'igberaga wa ti to, 'Gba t'a ba gb'asọ titun wọ; B'eni pe awọn kokoro, At'aguntan ko ti n wọ wọn. Wo arẹwa labalaba, Ati itanna pulpit; B'asọ mi ti wu ko pọ to, Ko t'abọ ti awọn wọnyi. Njẹ n ó ma fi ọkan mi wa, Ohun ọsọ t'o ju wọn lọ; Iwa rere at'otitọ, L'ọsọ to ju gbogb' ọsọ lọ. Nigba na l'emi y'o dara, Pupọ j'awọn kokoro lọ, Ọsọ awọn angel l'eyi, Ati t'Ọm' Ọlọrun pẹlu. Ki ti, ki gbo, ki sa titi, Ipara ko si le bajẹ, T'ojo t'ẹrun, bakan naa ni Lilo ki ba ẹwa jẹ. Eyi n ó ma wọ layé, Ki n le ma wọ l'ọrun pẹlu; Ọsọ t'o w'Ọlọrun l'eyi, Ogo ati ayọ Rẹ ni. AMIN

Hymn 679 – K'IYA wa, Efa, to d'ese | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia