Hymn 678 – IYA t'o ru mi fun osu mewa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IYA t'o ru mi fun osu mewa" (C&S Hymn #678, Yoruba). IYA t'o ru mi fun osu mẹwa, Ti ko so mi kalẹ, O bi mi tan, o tun…
IYA t'o ru mi fun osu mẹwa, Ti ko so mi kalẹ, O bi mi tan, o tun pọn mi kiri, F'Ọdun mẹta toto. Iya, iya, iya, mo dupe, Ise re t'ọsan t'oru, Nijọ jijẹ, at'ijọ alaijẹ, Iya nitori mi. Gba mo s'aisan tal'o duro ti mi, T'o si gbe mi mora? Gba mo sokun, tani rẹ mi l'ẹkun, Iya, bi ko se 'wọ? Iya, iya, iya, mo dupe, Ise re t'ọsan t'oru, Nijọ jijẹ, at'ijọ alaijẹ, Iya nitori mi. Nigba ewe t'emi ko le sọrọ, Tani m'ohun mo fe? Gba mo n dagba, tani se 'tọju mi, Iya, iwọ ha kọ? Iya, iya, iya, mo dupe, Ise re t'ọsan t'oru, Nijọ jijẹ, at'ijọ alaijẹ, Iya nitori mi. Ororo ọyan iya ti mo yan, Ko le tan lara mi; Bi mo lowo, owo mi ko le ra, Ise re lori mi. Iya, iya, iya, mo dupe, Ise re t'ọsan t'oru, Nijọ jijẹ, at'ijọ alaijẹ, Iya nitori mi. Eyin ọrẹ tẹ ti sọ 'ya yin nu, Mo ki yin ku le de, Ati ẹyin t'iya yin wa layé, E f'opẹ f'Ọlọrun. Iya, iya, iya, mo dupe, Ise re t'ọsan t'oru, Nijọ jijẹ, at'ijọ alaijẹ, Iya nitori mi. Jẹ ka mura lati huwa rere, Bi ọmọ ọlọgbọn; Ka jọ Jesu ninu iwa pẹlẹ, Ka j'ọmọ to gbọran. Iya, iya, iya, mo dupe, Ise re t'ọsan t'oru, Nijọ jijẹ, at'ijọ alaijẹ, Iya nitori mi. AMIN Iya, iya, iya, mo dupe, Ise re t'ọsan t'oru, Nijọ jijẹ, at'ijọ alaijẹ, Iya nitori mi.
Hymn 678 – IYA t'o ru mi fun osu mewa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia