Hymn 677 – ORE kan mbe fun omode | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ORE kan mbe fun omode" (C&S Hymn #677, Yoruba). ỌRẸ kan mbẹ fun ọmọde, Loke ọrun lọhun, Ọrẹ ti ki yipada, T'ifẹ rẹ ko…
ỌRẸ kan mbẹ fun ọmọde, Loke ọrun lọhun, Ọrẹ ti ki yipada, T'ifẹ rẹ ko le ku; Ko dabi ọrẹ ayé, Ti mbajẹ lọdọdun; Orukọ Rẹ bi ọrẹ, Wo fun nigba gbogbo. Isinmi kan mbẹ f'ọmọde, Loke ọrun lohun; F'awọn t'o f'Olugbala, Ti n ke Abba Baba di Isinmi lọwọ 'yọnu, Lọw' ẹsẹ at'ewu; Nibi t'awọn ọmọde, Y'o sinmi titi lai. Ile kan mbẹ fun ọmọde, Loke ọrun lọhun; Nibi ti Jesu n jọba, Ile alafia! di Ko s'ile t'o jọ layé, T'a le fi sakawe; Ara ro 'lukuluku; Irora na dopin. Ade kan mbẹ fun ọmọde, Loke ọrun lọhun; Ẹni t'o ba n wo Jesu, Y'o ri na de; Ade t'o logo julọ, Ti y'o fi fun gbogbo Awọn ọrẹ rẹ layé; Awọn t'o fe nihin. Orin kan mbẹ fun ọmọde, Loke ọrun lọhun; Orin ti ko le su ni, B'o ti wu k'a ko to! Orin t'awọn angeli, Ko le ri ko titi; Krist ki s'Olugbala wọn, Ọba l'o jẹ fun wọn. Ẹwu kan mbẹ fun ọmọde, Loke ọrun lọhun; Harpu olohun didan! Imọpẹ isẹgun! Gbogbo ẹbun rere yi, L'a ni ninu Jesu; Ẹ wa ẹyin ọmọde, Ki wọn le jẹ tiyin. Amin
Hymn 677 – ORE kan mbe fun omode | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia