Hymn 672 – FUN iyin Olodumare | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "FUN iyin Olodumare" (C&S Hymn #672, Yoruba). FUN iyin Olodumare, L'a s'ẹda ahọn wa, L'awọn kan tilẹ kẹgan wa, K'a…

Hymn 672 – FUN iyin Olodumare | C&S Yoruba Hymnary
FUN iyin Olodumare, L'a s'ẹda ahọn wa, L'awọn kan tilẹ kẹgan wa, K'a s'adura fun wọn. Ifi-ni s'ẹsin ẹlẹya, Ko tọ n'ile-iwe, K'a si p'eniyan ni were S'ewu iparun ni. Ẹnikẹni t'o wu k'o se Ti ba n so 'sọkusọ, S'awọn mimọ, s'ohun mimọ, L'Oluwa y'o lu pa. 'Gbat' awọn 'mọ buburu ni, N fi Elisa s'ẹsin, Ti wọn ń kigbe soke, wi pé, Goke lọ, 'wọ apari. Lọgan k'Ọlọrun lu wọn pa? T'o ran beari meji? T'o fa wọn ya pẹrẹpẹrẹ, Titi wọn fi ke ku? Ibinu Rẹ ti l'ẹru to! S'awọn ọmọ-kọmọ; Fi ore-ọfẹ Rẹ, Baba, K'ahọn mi n'ijanu. AMIN

Hymn 672 – FUN iyin Olodumare | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia