Hymn 671 – EMI ko le gbagbe ojo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EMI ko le gbagbe ojo" (C&S Hymn #671, Yoruba). EMI ko le gbagbe ọjọ T'iya sọ fun mi jẹjẹ, pe Bi o ba d'ominira tan…

Hymn 671 – EMI ko le gbagbe ojo | C&S Yoruba Hymnary
EMI ko le gbagbe ọjọ T'iya sọ fun mi jẹjẹ, pe Bi o ba d'ominira tan Mase gbagbe ọjọ iya. Nigba ti mo rohun gbogbo, Ifẹ ti iya ni si mi, Ọrọ ifẹ ran mi leti, Pe ma gbagbe ọjọ iya. Emi ko le sai ma ranti, Gbogbo wahala iya mi; To n tọju mi tọsan toru, Ninu ebi ninu ayọ. Nigba ti mo rohun gbogbo, Ifẹ ti iya ni si mi, Ọrọ ifẹ ran mi leti, Pe ma gbagbe ọjọ iya. Iya wa ni onimọran; Baba wa ni oniranwọ, Awọn ti n se bi iya wa, Se wọn ko le jọ iya wa Nigba ti mo rohun gbogbo, Ifẹ ti iya ni si mi, Ọrọ ifẹ ran mi leti, Pe ma gbagbe ọjọ iya. N ó se baba, ki jọ baba, Gba 'po de mi, ki s'onipo, Sole de mi, ki s'onile, Alagbata s'ọja d'ọwọn. Nigba ti mo rohun gbogbo, Ifẹ ti iya ni si mi, Ọrọ ifẹ ran mi leti, Pe ma gbagbe ọjọ iya. Ẹyin iya, ẹ o jere ọmọ, Ẹyin baba, ẹ o jẹun ọmọ; Ẹnikan ki o gba 'se yin se, Ni agbara Edumare. Nigba ti mo rohun gbogbo, Ifẹ ti iya ni si mi, Ọrọ ifẹ ran mi leti, Pe ma gbagbe ọjọ iya. AMIN Nigba ti mo rohun gbogbo, Ifẹ ti iya ni si mi, Ọrọ ifẹ ran mi leti, Pe ma gbagbe ọjọ iya.

Hymn 671 – EMI ko le gbagbe ojo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia