Hymn 668 – B'OKIKI ija tile nkan | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "B'OKIKI ija tile nkan" (C&S Hymn #668, Yoruba). B'OKIKI ija tilẹ nkan, T'ariwo gb'ode kan, K'irẹpọ wa n'ile dara,…
B'OKIKI ija tilẹ nkan, T'ariwo gb'ode kan, K'irẹpọ wa n'ile dara, Ọmọ-Iya ki ja. Awọn ẹyẹ n'nu itẹ wọn, Ki ba ara wọn ja, Ohun itiju nla ha kọ, K'ọmọ-'ya ka rẹpọ. Ihalẹ- akọ- apara, Fari lasan-lasan, Kumọ ni da, a fa 'da yọ, A si bi'ku l'ọmọ Ise bilisi n'ibinu, Larin ọmọ iya, Ibinu ni Kaini fi lu, Arakunrin rẹ pa. Ibinu ọlọgbọn ki pẹ, A tan k'orun to wọ; Sugbọn t'asiwere a wa Titi d'ọjọ alẹ. Fi ẹsẹ inu-bibi wa, Ji wa, Oluwa wa, Ka f'ibinu ewe silẹ, Ka si dagba n'ifẹ. AMIN
Hymn 668 – B'OKIKI ija tile nkan | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia