Hymn 669 – B'O ti dun to lat' ewe lol | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "B'O ti dun to lat' ewe lol" (C&S Hymn #669, Yoruba). B'O ti dun to lat' ewe lọ! K'a fi ipa ọgbọn s'ọna, K'a je olotitọ…
B'O ti dun to lat' ewe lọ! K'a fi ipa ọgbọn s'ọna, K'a je olotitọ Ọmọ, K'arayé le f'ọkan tan wa. A ko le gbẹkẹl' opurọ, B'o tilẹ pada s'otitọ; B'eniyan se buburu kan, T'o si purọ: a di meji. B'iro ti j'ohun 'rira to, L'Ọlọrun fi han 'nu ọrọ Rẹ, Iku-oro Anania, Se n'tori 'rọ-pipa ni. Safira aya rẹ pẹlu, Bi o ti n jẹri ọkọ rẹ; L'ogedengbe ko l'o lule? Bẹ ki t'ọkọ t'aya ku si? Oluwa y'o n' inu didun S'ẹnikẹni ti n s'otitọ, Y'o si l'awọn opurọ lọ, Sinu adagun ina. Irọ gbogbo t'eniyan n pa, L'Ọlọrun n kọ s'inu iwe; N ó k'ahọn mi ni ijanu, Ki n ma ba ku s'ọrun egbe. AMIN
Hymn 669 – B'O ti dun to lat' ewe lol | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia