Hymn 665 – AWON Angeli ni orun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "AWON Angeli ni orun" (C&S Hymn #665, Yoruba). AWỌN Angẹli ni ọrun, Yin Ọ logo, Ọlọrun wa, Iwuwo ọpa 'binu Rẹ, N damu…

Hymn 665 – AWON Angeli ni orun | C&S Yoruba Hymnary
AWỌN Angẹli ni ọrun, Yin Ọ logo, Ọlọrun wa, Iwuwo ọpa 'binu Rẹ, N damu esu l'ọrun ẹgbẹ. Gbogbo ẹyin ọmọ-kọmọ, Asepe ati abura; Ẹ se 'ranti ofin kẹta, Kẹ bọwọ f'Okọ Ọlọrun. Wọn o se le duro, Baba, Niwaju agbara nla Rẹ! Awọn alaibẹru Ọlọrun, Yoo lọ si ọrun egbe! Nibi ti ki y'o si omi, Ti y'o pa oungbẹ ọfun wọn, Emi y'o ma yin Ọ titi, Bi n ó ti ma yin ni ọrun. Ibanujẹ nla ni fun mi Lati gbọ ọrọ buburu; Ti awọn ọmọkọmọ n sọ, Si Eledumare Baba! Gbogbo wọn ni n ó l'ọrẹ, Awọn alaibẹru Ọlọrun, Ti wọn n p'orukọ Rẹ lasan, Ti wọn mbura, ti wọn n sepe. AMIN

Hymn 665 – AWON Angeli ni orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia