Hymn 664 – ALABUKUN FUN l'omo na | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ALABUKUN FUN l'omo na" (C&S Hymn #664, Yoruba). ALABUKUN FUN l'ọmọ na, Lati igba ewe; Ti ki rin l'ọna iparun, Ti mbẹru…
ALABUKUN FUN l'ọmọ na, Lati igba ewe; Ti ki rin l'ọna iparun, Ti mbẹru Ọlọrun. K'a fi ara wa f'Ọlọrun, Lat' igba ewe dun; Ẹbun giga n'itanna jẹ, 'Gba to ba sẹsẹ n yo. K'a t'ewe bẹru Oluwa, Rọrun lọpọlọpọ; Bi ẹlẹsẹ ti n dagba to L'ọkan wọn si nle to. Ka gbọ ti isin Ọlọrun, Lati igba ewe, N'nu ewe pupọ ni a n yọ, A si fun-ni n' ipa Ọlọrun Olodumare, A f'ara wa fun Ọ, K'a jẹ tirẹ lat'ewe lọ, Titi d'opin ayé. K'isẹ adura at'iyin, Jẹ isẹ ayé mi; Lọjọ iku, k'yoo jẹ ki n yẹ, Lati f'ayọ r'ọrun. AMIN
Hymn 664 – ALABUKUN FUN l'omo na | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia