Hymn 066 – IGBALA ni, igbala ni | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IGBALA ni, igbala ni" (C&S Hymn #066, Yoruba). 1. IGBALA ni, igbala ni, Awa ẹlẹsẹ n fẹ; Nitori ninu buburu T'a se…

Hymn 066 – IGBALA ni, igbala ni | C&S Yoruba Hymnary
1. IGBALA ni, igbala ni, Awa ẹlẹsẹ n fẹ; Nitori ninu buburu T'a se l'awa n segbe. 2. Isẹ ọwọ wa ti a n se, O n wi nigba gbogbo, mp Pe, igbala ko si nibẹ Isẹ ko le gba ni. 3. Awa n sẹbọ, awa n rubọ, A n kọrin, a si n jo; Sugbọn a ko ri igbala, Ninu gbogbo wọnyi. 4. Nibo ni igbala gbe wa? Fi han ni, fi han ni; B'o wa loke, bi isalẹ, B'o ba mọ, wi fun wa. 5. Jesu ni se Olugbala, Jesu l'Oluwa wa; Igbala wa ni ọwọ Rẹ; Fun awa ẹlẹsẹ. 6. Wa nisinsin yii, wa tọrọ, Ifẹ wa ninu Rẹ; Ẹyin ti o buru l'O n pe; Ẹ wa gba igbala. AMIN

Hymn 066 – IGBALA ni, igbala ni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia