Hymn 067 – JESU Oba ogo dariji wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU Oba ogo dariji wa" (C&S Hymn #067, Yoruba). 1. JESU Ọba ogo dariji wa, Wo wa san ninu arun ẹsẹ gbogbo; 'Wọ to wo…
1. JESU Ọba ogo dariji wa, Wo wa san ninu arun ẹsẹ gbogbo; 'Wọ to wo awọn adẹtẹ 'gbani san, Jọwọ masai wo aisan wa gbogbo san Wọle, wọle, wọle w'ọdọ Jesu, Wọle wa, wọle, iwọ yoo gb'ade, A mọ daju p'awa yoo de Kenani Nibi ti Baba wa ti pese fun wa. 2. Ọlọrun Abram ati Isaaki, Ọlọrun Jakob jọwọ dabo bo wa, Jọwọ mu ọna wa tọ niwaju Rẹ, Ko si ranti gbogbo wa si rere. 3. Iwọ to wa pẹlu Sedrak, Mesak, Abẹdnigo ninu ina ileru, Jọwọ yọ wa ninu ina idẹkun esu, Ka le b'awọn Angẹl kọrin loke. 4. mf Ogo fun Baba, Ọmọ at'Ẹmi, To da ẹmi wa si di ọjọ oni, Jọwọ ran oluranlọwọ Rẹ si wa, Ki 'sẹgun jẹ tiwa lat'oni lọ. AMIN
Hymn 067 – JESU Oba ogo dariji wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia