Hymn 065 – ELESE wa s'orisun na | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ELESE wa s'orisun na" (C&S Hymn #065, Yoruba). 1. ẸLẸSẸ wa s'orisun na, Wa pẹlu 'banujẹ rẹ, Ri wọn sinu omi jijin, 'Wọ…
1. ẸLẸSẸ wa s'orisun na, Wa pẹlu 'banujẹ rẹ, Ri wọn sinu omi jijin, 'Wọ y'o r'irọrun nibẹ. Yara kalọ, mase duro, Isẹju kan le sọ ẹmi rẹ nu, Jesu n duro lati gba ọ, Anu mbẹ fun ọ loni. 2. Wa t'iwọ t'ẹru ẹsẹ rẹ, Jesu ti n duro de ọ; B'ẹsẹ rẹ pọn bi alari, Wọn yoo funfun bi sino. 3. Jesu Olugbala wi pé, Awọn ti o ba gbagbọ; Ti wọn si ronupiwada, Y'o r'iye gba lọdọ Rẹ. 4. Wa wẹ ninu orisun naa, F'eti si ohun ifẹ; Jẹ ki awọn Angẹli yọ, F'ẹlẹsẹ to yi pada AMIN
Hymn 065 – ELESE wa s'orisun na | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia