Hymn 64 – A de o, Baba Mimọ, k'o wa gba wa o | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A de o, Baba Mimọ, k'o wa gba wa o" (C&S Hymn #64, Yoruba). 1. A de o, Baba Mimọ, k'o wa gba wa o, A de o, Ọmọ Mimọ,…
1. A de o, Baba Mimọ, k'o wa gba wa o, A de o, Ọmọ Mimọ, k'o wa gba wa o. 2. A de o, Ẹmi Mimọ k'o wa gba wa o A de o, Mẹtalọkan a ke pe Ọ o. 3. A de o Mẹtalọkan wa ba wa pe o, A de o, a juba k'iba sẹ fun wa. 4. A de o, f'ẹsẹ ọkunrin ji wọn o, A de o, f'ẹsẹ obinrin ji wọn o. 5. A de o, f'ẹsẹ ọmọde ji wọn o, A de o, t'ọmọde t'agba be Ọ. 6. A de o, Alanu a ke pe Ọ o. A de o, Mẹtalọkan dariji wa o. 7. A de o f'agbara Ẹmi Rẹ fun wa, A de o, k'O se wa l'ẹni 'bukun o. 8. A de o, fun gbogbo awọn ariran, A de o, ma j'esu fi 'ran han wọn o. 9. A de o, fun gbogbo 'sisẹ nin'agbo; A de o, f'Ẹmi ọtun Rẹ wo wọn o. 10. A de o, Mẹtalọkan rant' awọn agan wa, A de o, jẹ ki wọn fi'nu soyun o. 11. A de o, Jesu rant' awọn aboyun wa, A de o, jẹ ki wọn bi tayọtayọ o. 12. A de o, Mẹtalọkan f'isọ Rẹ sọ wa, A de o, Mẹtalọkan dabo bo wa o. 13. A de o, Mẹtalọkan sure fun wa o, A de o, ma jẹ k'a rahun layé wa. 14. A de o, Onikẹ ko wa sikẹ wa, A de o, Alayọ ko fun wa layọ. 15. A de o, Alagbara fun wa lagbara, A de o, ma jẹ k'esu ri wa gbe se. 16. A de o, ma jẹ k'ọmọ Rẹ sẹku o, A de o, ma jẹ k'ọmọ Rẹ gbọn ku o. 17. A de o, Ẹrintunde pa wa lẹrin o, A de o, ko jẹ k'ọjọ wa d'alẹ o. 18. A de o, Mẹtalọkan Ọba Alasẹ, A de o, bukun wa karikari o. ASẸ, AMIN, O, KO SẸ
Hymn 64 – A de o, Baba Mimọ, k'o wa gba wa o | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia