Hymn 657 – IRE t' a su ni Eden' | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IRE t' a su ni Eden'" (C&S Hymn #657, Yoruba). IRE t' a su ni Eden', N' igbeyawo 'kini, Ibukun t' a bukun won O wa…

Hymn 657 – IRE t' a su ni Eden' | C&S Yoruba Hymnary
IRE t' a su ni Eden', N' igbeyawo 'kini, Ibukun t' a bukun won O wa sibesibe. Sibe titi di oni, N' igbeyawo Kristian; Olorun wa larin wa, Lati sure fun wa. Ire, kin won le ma bi, Ki nwon si le ma re; Ki nwon n' idapo mimo T' enikan k'yo le tu. Ba ni pe, Baba, si fa Obirin yi f' oko; Bi o ti Efa fun Adam l' ojo kini. Ba ni pe Olugbala, Si so owo won po, B' O ti so ara Re po Pelu enia Re. Ba wa pe, Emi Mimo, F' ibukun Re fun won; Si se won ni asepe, Gege b' o ti ma se. Fi nwon s' abe abo Re, K' ibi kan ma ba won; 'Gba nwon npara ile Re, Ma toju okan won. Pelu won l' oj' aiye won, At' oko at' aya; Titi nwon o d' odo Re N' ile ayo l' orun.

Hymn 657 – IRE t' a su ni Eden' | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia