Hymn 658 – JESU f'ara han nitoto | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU f'ara han nitoto" (C&S Hymn #658, Yoruba). JESU f'ara han nitotọ Nibi ase 'yawo, Oluwa, awa bẹ Ọ, wa, F'ara Rẹ…
JESU f'ara han nitotọ Nibi ase 'yawo, Oluwa, awa bẹ Ọ, wa, F'ara Rẹ han nihin. Fi ibukun Rẹ fun awọn Ti o dawọpọ yi; F'ojurere wo 'dapọ wọn, Si bukun ẹgbẹ wọn. F'ẹbun ifẹ kun aya wọn, Fun wọn n'itẹlọrun, Fi alafia Rẹ kun wọn, Si busi ini wọn F'ifẹ mimọ sọ wọn d'ọkan, Ki wọn f'ifẹ Kristi, Mu aniyan ile fẹrẹ Nipa ajumose. Jẹ ki wọn ran 'ra wọn lọwọ, Ninu ibugbe wọn; Ki wọn si ni ọmọ rere, Ti y'o gbe 'le wọn ro. AMIN
Hymn 658 – JESU f'ara han nitoto | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia