Hymn 656 – IFE pipe t'o tayo ero eda | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IFE pipe t'o tayo ero eda" (C&S Hymn #656, Yoruba). IFẸ pipe t'o tayọ ero ẹda, L'ẹbẹ l'a kunlẹ niwaju 'tẹ Rẹ, Jọwọ…

Hymn 656 – IFE pipe t'o tayo ero eda | C&S Yoruba Hymnary
IFẸ pipe t'o tayọ ero ẹda, L'ẹbẹ l'a kunlẹ niwaju 'tẹ Rẹ, Jọwọ f'ifẹ ti ki y'o lopin sarin, Awọn t'Iwọ so sọkan pọ lailai. Iye pipe jọwọ f'aya wọn balẹ, Nipa ifẹ ati 'gbagbọ yiye, Ti suru, ireti, at'ifarada, Pelu igbẹkẹle ti ko le yẹ. Jọ fun wọn l'ayọ ti y'o m'ayé wọn dun, Alafia ti y'o sẹgun ija, Si f'ifẹ ayérayé ati Iye Kun ọkan wọn titi d'ọjọ ogo. AMIN IRE ta su ni Eden IRE ta su ni Eden, N'igbeyawo kinni, Ibukun t'a bukun wọn, O wa sibẹ sibẹ. Sibẹ titi di oni, N'igbeyawo Kristian, Ọlọrun wa larin wa, Lati sure fun wa. Ire ki wọn le ma bi Ki wọn ko si ma rẹ, Ki wọn ni 'dapọ mimọ, T'ẹnikan k' yo le tu. Ba ni pe, Baba, si fa Obinrin yi f'ọkọ, Bi O ti fa Efa fun, Adam lọjọ kini. Ba wa pe, Immanueli, Si so ọwọ wọn pọ, B'ẹda meji ti papọ, Lara ijinlẹ Rẹ. Ba wa pe, Ẹmi Mimọ , F'ibukun Rẹ fun wọn; Si se wọn ni asepe, Gẹgẹ b'O ti ma se. Fi wọn sabẹ abo Rẹ, K'ibi kan ma ba wọn; 'Gba wọn n para ile Rẹ, Ma tọju ọkan wọn. Pẹlu wọn l'ọj' ayé wọn, At'ọkọ at'aya; Titi wọn o de ọdọ Rẹ, N'ile ayọ l'ọrun. AMIN

Hymn 656 – IFE pipe t'o tayo ero eda | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia