Hymn 655 – BABA Olodumare | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA Olodumare" (C&S Hymn #655, Yoruba). BABA Olodumare, A n tọrọ anu Rẹ; S'ori arakunrin yi, At'arabinrin yi. S'ọkan…
BABA Olodumare, A n tọrọ anu Rẹ; S'ori arakunrin yi, At'arabinrin yi. S'ọkan ọkọ oun aya, F'ibẹru Rẹ fun wọn, Ki wọn n'ifẹ ara wọn, Ni ọjọ ayé wọn. Ran esi rere si wa, K'awa si le mọ pe, Gbogbo eto oni yi, Jẹ didun inu Rẹ. Iru ọjọ bi oni, Jehovah Jireh wa; Wa lati f'ibukun fun, Awọn eniyan Rẹ. Se wọn ni abiyamọ, Ki wọn ko si ma rẹ, Ẹranko ati ẹyẹ, Wọn mbi lọpọlọpọ. F'ayọ oun alafia, Pẹlu itẹlọrun; S'ile awọn ọmọ Rẹ, Pese fun aini wọn. Ki adun lọna gbogbo, Yi wọn ka lat'oni; K'ire ma ba wọn titi, K'a ayé ma le ya wọn. Baba Onibu-ọrẹ, Ran ore Rẹ si wọn; Mu wọn bori gbogbo ọta, Si jẹ Ọlọrun wọn. AMIN
Hymn 655 – BABA Olodumare | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia