Hymn 640 – A! Ko s'alabaro l'aye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A! Ko s'alabaro l'aye" (C&S Hymn #640, Yoruba). A! Ko s'alabaro l'ayé, Mase ronu nitori, Ti ko si alabaro mọ, Jesu ju…
A! Ko s'alabaro l'ayé, Mase ronu nitori, Ti ko si alabaro mọ, Jesu ju Iya oun Baba. Tu 'ju rẹ ka, Sa gbẹkẹle Ọlọrun. A! ko s'alabaro l'ayé, Mase bẹru, bi ayé, Ba n yi o ka ninu ẹru, Jesu yoo wa pẹlu rẹ, Kẹ pe Jesu, Iwọ yoo sẹgun wọn. A! ko s'alabaro l'ayé, Ma foya b'igbi ayé, Ba bo ọ mọlẹ b'okun nla, Iwọ yoo bori dandan, A! ma bẹru, Jesu yoo wa pẹlu rẹ. A! ko s'alabaro l'ayé, Ma binu b'ayé n kẹgan, T'o si n sata rẹ nitori, T'iwọ ko ni ẹnikan, Sa gbadura , Ibanujẹ yoo dayọ. A! ko s'alabaro l'ayé, Ma roju b'ebi n pa ọ, Ọlọrun to mbọ eera 'lẹ, Oun na y'o si bọ ọ yo. Gbẹkẹle mi, Eyi l'asẹ Jehofa. A! ko s'alabaro l'ayé, Ma kanu 'po rẹ l'ayé, Ọlọrun yoo le esinsin, Fun malu ti ko n'iru. Sa wo Jesu, Ẹkun re yoo si d'ayọ. Jesu nikan l'Alabaro, Oun l'Ọrẹ ti ki dani, Oun ni Ọkọ awọn opo, Oun Baba 'laini baba. Sa gbẹkẹle, Oun o si ran ọ lọwọ. AMIN
Hymn 640 – A! Ko s'alabaro l'aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia