Hymn 639 – OLORUN gbogbo araye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN gbogbo araye" (C&S Hymn #639, Yoruba). ỌLỌRUN gbogbo arayé, Iwọ t'o pe ki 'mọlẹ k'o wa, Iwọ t'o pe k'eweko hu,…

Hymn 639 – OLORUN gbogbo araye | C&S Yoruba Hymnary
ỌLỌRUN gbogbo arayé, Iwọ t'o pe ki 'mọlẹ k'o wa, Iwọ t'o pe k'eweko hu, O si ri bẹ nipa asẹ Rẹ. Gbọ t'emi, gbọ t'emi, Gbọ t'emi, Ọba awimayẹhun, Gbọ t'emi (3ce) Ọba a-wi-ma-yẹhun. Ọlọrun t'o gbọ ti Mose, T'apa awọn Ọba ko fi ka, Ọlọrun t'o gbọ t'Elijah, T'o si doju t'awọn ọta rẹ. Gbọ t'emi, gbọ t'emi, Gbọ t'emi, Ọba awimayẹhun, Gbọ t'emi (3ce) Ọba a-wi-ma-yẹhun. Ọlọrun t'o pe k'okun wa, T'ọmọ arayé ko ri 'di rẹ, Ọlọrun t'o pe k'ọsa wa, T'ọmọ arayé ko ridi rẹ. Gbọ t'emi, gbọ t'emi, Gbọ t'emi, Ọba awimayẹhun, Gbọ t'emi (3ce) Ọba a-wi-ma-yẹhun. Ọlọrun t'o la 'gan ninu, Baba awọn alaini baba, Ọlọrun t'o gbọ ti Estha, T'o si gbe leke awọn ọta rẹ. Gbọ t'emi, gbọ t'emi, Gbọ t'emi, Ọba awimayẹhun, Gbọ t'emi (3ce) Ọba a-wi-ma-yẹhun. Kérúbù pẹlu Séráfù, Ẹ f'ogo fun Baba loke, Fun isẹgun t'o n se fun wa, Nigba t'awọn ayé fẹ kẹgan. Gbọ t'emi, gbọ t'emi, Gbọ t'emi, Ọba awimayẹhun, Gbọ t'emi (3ce) Ọba a-wi-ma-yẹhun. Ẹ f'ogo fun Baba loke, A wa si f'ogo f'Ọmọ Rẹ, A f'ogo fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan ni ọpẹ yẹ fun. Gbọ t'emi, gbọ t'emi, Gbọ t'emi, Ọba awimayẹhun, Gbọ t'emi (3ce) Ọba a-wi-ma-yẹhun. AMIN Gbọ t'emi, gbọ t'emi, Gbọ t'emi, Ọba awimayẹhun, Gbọ t'emi (3ce) Ọba a-wi-ma-yẹhun.

Hymn 639 – OLORUN gbogbo araye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia