Hymn 641 – F'ORE-ofe Re ba wa gbe | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "F'ORE-ofe Re ba wa gbe" (C&S Hymn #641, Yoruba). F'ORE-ọfẹ Rẹ ba wa gbe, Jesu Olugbala; Ki ẹni arekereke, K'o ma le…
F'ORE-ọfẹ Rẹ ba wa gbe, Jesu Olugbala; Ki ẹni arekereke, K'o ma le koju wa. F'ọrọ mimọ Rẹ ba wa gbe, Jesu iyebiye: K'a ri igbala oun iye, Lọhun bi nihinyi. Fi 'bukun Tirẹ ba wa gbe, Oluwa Olore; Fi ẹbun ọrun rere Rẹ, Fun wa l'ọpọlọpọ. Fi 'pamọ Tirẹ ba wa gbe, Iwọ Alagbara; K'awa k'o le sa ọta ti, K'ayé k'o ma de wa. Fi otitọ Rẹ ba wa gbe, Ọlọrun Olore; Ninu 'pọnju, wa ba wa rẹ, Mu wa fi ori ti. F'alafia Rẹ ba wa gbe, Nigba t'iku ba de ; N'isẹju na, sọ fun wa pe, Igbala yin ti de. AMIN
Hymn 641 – F'ORE-ofe Re ba wa gbe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia