Hymn 635 – 'GBATI Samuel' ji | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "'GBATI Samuel' ji" (C&S Hymn #635, Yoruba). 'GBATI Samuel' ji, T'o gb'ohun Ẹlẹda Ni gbolohun kọkan, Ayọ rẹ ti pọ to!…

Hymn 635 – 'GBATI Samuel' ji | C&S Yoruba Hymnary
'GBATI Samuel' ji, T'o gb'ohun Ẹlẹda Ni gbolohun kọkan, Ayọ rẹ ti pọ to! Ibukun ni f'ọmọ t'o ri, Ọlọrun nitosi rẹ bẹ. B'Ọlọrun ba pe mi, Pe, ọrẹ mi ni Oun, Ayọ mi y'o ti to! N ó si f'eti silẹ, N ó sa f'ẹsẹ t'o kere ju, B'Ọlọrun sunmọ 'tosi bẹ. Ko ha mba ni sọrọ? Bẹni, n'nu ọrọ Rẹ, O n pe mi lati wa, Ọlọrun Samuel; N'nu Iwe na ni mo ka pe, Ọlọrun Samuel n pe mi. Mo le f'ori pamọ, S'abẹ itọju Rẹ, Mo mọ p'Ọlọrun mbẹ, Lọdọ mi n'gba gbogbo; O yẹ k'ẹru ẹsẹ ba mi, 'Tor' Ọlọrun sunmọ 'tosi. 'Gba mba n ka ọrọ Rẹ, Ki n wi bi Samuel pe; Ma wi, Oluwa mi, Emi y'o gbọ Tirẹ, 'Gba mo ba si wa n'ile Rẹ, Ma wi, 'tori 'ransẹ Rẹ n gbọ. AMIN

Hymn 635 – 'GBATI Samuel' ji | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia