Hymn 636 – OLUWA ti pe mi sinu Egbe Kerubu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA ti pe mi sinu Egbe Kerubu" (C&S Hymn #636, Yoruba). OLUWA ti pe mi sinu Ẹgbẹ Kérúbù, Esu n ba mi ja, ẹsẹ n ba mi…

Hymn 636 – OLUWA ti pe mi sinu Egbe Kerubu | C&S Yoruba Hymnary
OLUWA ti pe mi sinu Ẹgbẹ Kérúbù, Esu n ba mi ja, ẹsẹ n ba mi ja Ayé n ba mi ja, sugbọn ẹsẹ mi ko yẹ, Ninu Ẹgbẹ Kérúbù. Oluwa ti pe mi sinu Ẹgbẹ Séráfù, Afẹfẹ n fẹ pọ, ojo si n rọ pọ Iji si n ja, sugbọn ẹsẹ mi ko yẹ, Ninu Ẹgbẹ Séráfù. Oluwa ti pe mi sin' Ẹgb' Aladura, Inu mi dun si, ọkan mi yo si Ero mi tẹ si, sugbọn ẹsẹ mi ko yẹ, Nin' Ẹgbẹ Aladura. Oluwa ti pe mi sin' Ẹgbẹ Kọmiti, Inu mi dun si, ẹsẹ mi lọ si Ero mi tẹ si, sugbọn ẹsẹ mi ko yẹ Nin' Ẹgbẹ Kọmiti. Oluwa ti pe mi sin' Ẹgbẹ Akọrin, Ori mi wu si, ohun mi la si Ijọ mi tẹ si, sugbọn ẹsẹ mi ko yẹ Nin' Ẹgbẹ Akọrin. Oluwa ti pe mi sin' Ẹgbẹ Bibeli, Baba n gbọ temi, Ọmọ n gbọ temi Emi n gbọ temi, nitori naa mo r'ayọ, Nin' Ẹgbẹ Bibeli. Oluwa ti gbe mi sori apata, Apata Mimọ ni, Apata didan ni, Jesu l'Apata na, nitori naa mo duro, Le Krist' Apata. AMIN

Hymn 636 – OLUWA ti pe mi sinu Egbe Kerubu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia