Hymn 626 – NI INU airije re, gbekele Jesu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "NI INU airije re, gbekele Jesu" (C&S Hymn #626, Yoruba). NI INU airijẹ re, gbẹkẹle Jesu, N'nu hila-hilo ayé, gbẹkẹle…
NI INU airijẹ re, gbẹkẹle Jesu, N'nu hila-hilo ayé, gbẹkẹle Jesu, Mase gbẹkẹle eniyan, sugbọn gbẹkẹle Jesu, Oun nikan lo le gba ọ, sa gbẹkẹ rẹ le. Ẹni t'o n pese fun era Oun na ko le bo o ti; Bi o ti wu k'o le to, Gbẹkẹle Jesu. Ẹyin Om' Ogun 'gbala yi, gbẹkẹle Jesu, Ẹ ke Hosanna f'Ọba ọmọ ninu Dafidi, Ẹni t'O ni kọkọrọ iku ati iye lọwọ; Oun nikan lo le gba ọ, sa ma se'fẹ Rẹ, Ẹni t'o n pese fun era Oun na ko le bo o ti; Bi o ti wu k'o le to, Gbẹkẹle Jesu. Ẹyin Leader wa ọwọn, ẹ ku 'sẹ Ẹmi; Jah yoo sọ ile ati ọna yin, Sa ma s'otitọ, Jẹ ki iwa rere yin han fun gbogbo awọn ẹda, Ogun ọrun yoo jẹri yin, ẹyin o gb'ade ogo Ẹni t'o n pese fun era Oun na ko le bo o ti; Bi o ti wu k'o le to, Gbẹkẹle Jesu. Ẹyin Ẹgbẹ Aladura, ẹ ma bohun mọ Sisẹ nigba ti i se ọsan, nitori oru mbọ, Gbe ida 'sẹgun rẹ s'oke, ẹ mase b'oju w'ẹyin, Ma gbẹkẹ rẹ le eniyan, tẹju mọ Jesu. Ẹni t'o n pese fun era Oun na ko le bo o ti; Bi o ti wu k'o le to, Gbẹkẹle Jesu. Ẹyin Ọmọ Ẹgbẹ Akọrin, ẹ tun ohun yin se Orin ni ẹ o ma ko titi n'ile Baba ọrun, Jesu yoo mu yin de'le lọ si ilu mimọ l'oke; Lati pẹlu ogun ọrun ti yin Ọd'aguntan. Ẹni t'o n pese fun era Oun na ko le bo o ti; Bi o ti wu k'o le to, Gbẹkẹle Jesu. Ẹyin Ọm' Ẹgbẹ Séráfù ati Kérúbù, Ẹmi Mimọ yoo ma sọ yin, ma bẹru ọta, Agbara tit' oke wa orin 'sẹgun l'a o ma kọ, Ogo fun Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ. Ẹni t'o n pese fun era Oun na ko le bo o ti; Bi o ti wu k'o le to, Gbẹkẹle Jesu. AMIN Ẹni t'o n pese fun era Oun na ko le bo o ti; Bi o ti wu k'o le to, Gbẹkẹle Jesu.
Hymn 626 – NI INU airije re, gbekele Jesu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia