Hymn 627 – L'EKAN mo jina s'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "L'EKAN mo jina s'Oluwa" (C&S Hymn #627, Yoruba). L'ẸKAN mo jina s'Oluwa, Mo n fi iwa mi bi ninu, Sugbọn Jesu ti gba…

Hymn 627 – L'EKAN mo jina s'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
L'ẸKAN mo jina s'Oluwa, Mo n fi iwa mi bi ninu, Sugbọn Jesu ti gba mi, Halleluyah! A, bi o ti dun to, Dun to, dun to, dun to, A, bi o ti dun to, Ki Jesu ma gbe inu mi. Ibinu ati 'runu mi, Ẹwọn ti Esu fi de mi, Jesu ti ja ide na, Halleluyah! A, bi o ti dun to, Dun to, dun to, dun to, A, bi o ti dun to, Ki Jesu ma gbe inu mi. Ifẹkufẹ kun ọkan mi, Pẹlu igberaga gbogbo, In' Ẹmi ti jo wọn, Halleluyah! A, bi o ti dun to, Dun to, dun to, dun to, A, bi o ti dun to, Ki Jesu ma gbe inu mi. Mo bọ lọwọ irẹwẹsi, Lọwọ ko gbona ko tutu, Ẹ ba mi yin Oluwa, Halleluyah! A, bi o ti dun to, Dun to, dun to, dun to, A, bi o ti dun to, Ki Jesu ma gbe inu mi. Mo n kọrin si lojojumọ, Mo n yọ mo si tun n fo s'oke, Nipa 'gbara Ẹmi, Halleluyah! A, bi o ti dun to, Dun to, dun to, dun to, A, bi o ti dun to, Ki Jesu ma gbe inu mi. Ẹjẹ 'yebiye wẹ mi mọ, Omi iye n san ninu mi, Igbala mi di kikun, Halleluyah! A, bi o ti dun to, Dun to, dun to, dun to, A, bi o ti dun to, Ki Jesu ma gbe inu mi. Ẹyin ara at'ọrẹ mi, Tani ko fẹ ri igbala, Ọfẹ ni l' ọdọ Jesu, Halleluyah! A, bi o ti dun to, Dun to, dun to, dun to, A, bi o ti dun to, Ki Jesu ma gbe inu mi. AMIN A, bi o ti dun to, Dun to, dun to, dun to, A, bi o ti dun to, Ki Jesu ma gbe inu mi.

Hymn 627 – L'EKAN mo jina s'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia