Hymn 625 – ORE aye ki lo jamo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ORE aye ki lo jamo" (C&S Hymn #625, Yoruba). ỌRẸ ayé ki lo jamọ, Ohun asan ni mo mọ si, Ko si alanu bi Jesu, Alawo kọ,…

Hymn 625 – ORE aye ki lo jamo | C&S Yoruba Hymnary
ỌRẸ ayé ki lo jamọ, Ohun asan ni mo mọ si, Ko si alanu bi Jesu, Alawo kọ, Ọlọrun ni, Adawunse kọ, Ọlọrun ni, Eniyan kọ, Ọlọrun ni. O yẹ ki n fi Jesu s'ọrẹ, Ko si ọrẹ kan bi Jesu, Jesu to fẹ wa d'oju 'ku, Babalawo kọ Ọlọrun ni, Awolẹ kọ, Ọlọrun ni, Eniyan kọ Ọlọrun ni. Nko ni ẹni ti mba ke pe, Mo wo 'waju, mo wo ẹhin, Ko tilẹ si alabaro, Onisegun kọ, Ọlọrun ni, Awolẹ kọ, Ọlọrun ni, Eniyan kọ, Ọlọrun ni. Sugbọn mo rọ mọ Ọ Jesu, Emi ki yo fi Ọ silẹ; Jesu, ma sai ran mi lọwọ, Alawo kọ, Ọlọrun ni, Akunlẹyan lo mba mi ja. 'Gbati mo joko n'ile mi, Esu wa d'ẹru b'ọkan mi, Sugbọn Jesu gbe mi leke, Wọn ni mo ku l'arayé sọ, Wọn l'o ti ku larayé sọ, Sugbọn Jesu da mi silẹ. Alairise, ko ma binu, Alaisan ma sọ 'reti nu, Jesu yoo mu yin lara da, Alawo kọ, Ọlọrun ni, Onisegun kọ, Ọlọrun ni, Eniyan kọ, Ọlọrun ni. K'a f'ogo fun Baba l'oke, K'a f'ogo fun Ọmọ pẹlu, Ogo ni fun Mẹtalọkan. Ọlọsanyin kọ, Ọlọrun ni, Aworawọ kọ, Ọlọrun ni, Jesu nikan lo to ke pe. AMIN

Hymn 625 – ORE aye ki lo jamo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia