Hymn 624 – MO gb'ohun Re ninu ala mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "MO gb'ohun Re ninu ala mi" (C&S Hymn #624, Yoruba). MO gb'ohun Rẹ ninu ala mi, Ohun kẹlẹkẹlẹ; Ohun ti n sọ 'fẹ…
MO gb'ohun Rẹ ninu ala mi, Ohun kẹlẹkẹlẹ; Ohun ti n sọ 'fẹ t'Oluwa, Ifẹ irapada; Mo tẹ'ti lelẹ lati gbọ, O si ya mi lẹnu, Bi mo titẹ 'ti le 'lẹ to, Jọ jẹ ki n roju Rẹ. Jọ jẹ ki n roju Rẹ (2) Bi mo ti tẹ'ti le'lẹ to, Jọ jẹ ki n roju Rẹ. Ninu Wahala ayé mi, Mo ba Jesu pade, Ti O si gba mi niyanju, Lati ma gbadura; Mo tẹ 'ti le'lẹ lati gbọ, O si mu 'nu mi dun, O si tun ki mi l'aya pe, Ki n sa ma gba adura. Ki n sa gba 'dura (2) O si tun ki mi l'aya pe, Ki n sa ma gba adura. Olodumare jọ gba wa, Awa Ẹgbẹ Séráfù, Nigba ti wahala ba de, Jọ gbọ adura wa; Ran awọn Kérúbù si wa, Lati ran wa lọwọ, Ki O si tẹ'ti si igbe wa, K'O gbọ adura wa. K'O gbọ adura wa(2) Ki O si tẹ'ti si igbe wa. K'O gbọ adura wa. AMIN K'O gbọ adura wa(2) Ki O si tẹ'ti si igbe wa. K'O gbọ adura wa.
Hymn 624 – MO gb'ohun Re ninu ala mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia