Hymn 623 – OJO nla l'ojo ti mo yan | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OJO nla l'ojo ti mo yan" (C&S Hymn #623, Yoruba). ỌJỌ nla l'ọjọ ti mo yan Olugbala l'Ọlọrun mi, O yẹ ki ọkan mi ma yọ,…
ỌJỌ nla l'ọjọ ti mo yan Olugbala l'Ọlọrun mi, O yẹ ki ọkan mi ma yọ, Ko si ro ihin na kalẹ. Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu; O kọ mi ki n ma gbadura, Ki n ma sọra, ki n si ma yọ, Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu. Isẹ igbala pari na, Mo di t'Oluwa mi loni, Oun lo pe mi ti mo si jẹ, Mo f'ayọ j'ipe mimọ na. Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu; O kọ mi ki n ma gbadura, Ki n ma sọra, ki n si ma yọ, Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu. Ẹjẹ mimọ yi ni mo jẹ, F'Ẹni to yẹ lati fẹran; Jẹ kọrin didun kun 'le Rẹ, Nigba mo ba n lọ sin nibẹ. Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu; O kọ mi ki n ma gbadura, Ki n ma sọra, ki n si ma yọ, Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu. Sinmi aiduro ọkan mi, Sinmi le Jesu Oluwa; Tani jẹ wi pé ayé dun, Ju ọdọ awọn Angeli. Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu; O kọ mi ki n ma gbadura, Ki n ma sọra, ki n si ma yọ, Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu. Ẹyin ọrun, gbọ ẹjẹ mi, Ẹjẹ mi ni ojojumọ; Em'o ma sọ d'ọtun titi, Iku y'o fi mu mi re 'le. Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu; O kọ mi ki n ma gbadura, Ki n ma sọra, ki n si ma yọ, Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu. AMIN Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu; O kọ mi ki n ma gbadura, Ki n ma sọra, ki n si ma yọ, Ọjọ nla l'ọjọ na! Ti Jesu wẹ ẹsẹ mi nu.
Hymn 623 – OJO nla l'ojo ti mo yan | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia