Hymn 613 – DURO, omo ogun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "DURO, omo ogun" (C&S Hymn #613, Yoruba). DURO, ọmọ ogun, F'ẹnu rẹ sọ f'ayé; Si jẹjẹ pe ofo l'ayé, Nitori Jesu re. Dide…

Hymn 613 – DURO, omo ogun | C&S Yoruba Hymnary
DURO, ọmọ ogun, F'ẹnu rẹ sọ f'ayé; Si jẹjẹ pe ofo l'ayé, Nitori Jesu re. Dide k'a baptis' rẹ, K'a wẹ ẹsẹ rẹ nu, Wa b'Ọlọrun da majẹmu, Sọ 'gbagbọ rẹ loni Tirẹ ni Oluwa, At' ijọba ọrun: Sa gb'ami yi siwaju rẹ, Ami Oluwa rẹ. 'Wọ k'ise t'ara rẹ, Bikose ti Kristi; A kọ orukọ rẹ pọ mọ, Awọn mimọ 'gbani. Ni hamọra Jesu, Kọju‘ja si Esu; B'o ti wu k'ogun na le to, Iwọ ni o sẹgun. Ade didara ni, Orin na, didun ni, 'Gba t'a ba ko ikogun jọ, S'ẹsẹ Olugbala. AMIN

Hymn 613 – DURO, omo ogun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia