Hymn 612 – OHUN aye b'aye lo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OHUN aye b'aye lo" (C&S Hymn #612, Yoruba). OHUN ayé b'ayé lọ, Kérúbù, Séráfù; Ilu ti a tẹ sori oke, A ko le fara sin.…
OHUN ayé b'ayé lọ, Kérúbù, Séráfù; Ilu ti a tẹ sori oke, A ko le fara sin. Jẹ ka soto (3) Ka le ri 'gbala nikẹyin. Ohun ayé b'ayé lọ, Ẹ ranti ti aya Loti, Ti o boju wo ẹhin; Ti o fi di ọwọn iyọ Jẹ ka soto (3) Ohun ayé b'ayé lọ, Ẹ ranti ọjọ Mose, Ti Farao fi ri s'okun, Ti Israel fi ri igbala. Jẹ ka sotọ (3) Ohun ayé b'ayé lọ, Ẹ ranti Ọjọ Noah, T'ọmọ eniyan fi n pẹgan, Ti ẹranko fi ri igbala Jẹ ka sotọ (3) Ẹyin Ẹgbẹ Oloye, At'ẹyin ẹgbẹ Mary; Baba yoo wa pẹlu yin, Yoo di yin lamure ododo. Jẹ ka sotọ (3) Ẹyin Ẹgbẹ Martha, Ati Ayaba Esther, Ẹ mura la ti sisẹ yin, Baba yoo se iranwọ Jẹ ka sotọ (3) Ẹyin Ẹgbẹ Akọrin, Ati 'Tan-lẹhin Jesu; Ẹ mura lati sisẹ yin, Jesu yoo se iranwọ Jẹ ka sotọ (3) Mose Orimọlade, O ti lọ soke ọrun; O dapọ mọ awọn Angel, O ti gbade Ogo. Jẹ ka sotọ (3) Ẹyin Ẹgb' Aladura, Ẹ ku asẹyinde; Baba yoo tu yin ninu, Yio gb'ọwọ yin soke. Jẹ ka sotọ (3) Ogo ni fun Baba wa, Ogo ni fun Ọmọ Rẹ, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan lailai. Jẹ ka sotọ (3) AMIN
Hymn 612 – OHUN aye b'aye lo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia