Hymn 611 – WA sodo Jesu, mase duro | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "WA sodo Jesu, mase duro" (C&S Hymn #611, Yoruba). WA sọdọ Jesu, mase duro, L'ọrọ Rẹ l'O ti f'ọna han wa; O duro ni…
WA sọdọ Jesu, mase duro, L'ọrọ Rẹ l'O ti f'ọna han wa; O duro ni arin wa loni, O n wi jẹjẹ pe Wa Ipade wa yoo jẹ ayọ, Gba ọkan wa ba bọ lọwọ ẹsẹ; T'a o si wa pẹlu Rẹ Jesu, Ni ile wa lailai. Jẹ k'ọmọde wa, A gbohun Rẹ, Jẹ k'ọkan gbogbo ho fun ayọ, Ki a si yan Oun l'ayanfẹ wa, Ma duro sugbọn wa, Ipade wa yoo jẹ ayọ etc. Tun ro O wa pẹlu wa loni, F'eti s'ofin Rẹ, k'o si gbagbọ, Gbọ b'ohun Rẹ ti n wi pẹlẹ, pe, Ẹyin ọmọ mi wa. Ipade wa yoo jẹ ayọ, Gb'ọkan wa ba bọ lọwọ ẹsẹ, T'a o si wa pẹlu Rẹ Jesu, Ni ile wa lailai. AMIN
Hymn 611 – WA sodo Jesu, mase duro | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia