Hymn 614 – OHUN ti n dun l'aginju | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OHUN ti n dun l'aginju" (C&S Hymn #614, Yoruba). OHUN ti n dun l'aginju, Ohun alore ni, Gbọ b'o ti n dun rara pe Ẹ…

Hymn 614 – OHUN ti n dun l'aginju | C&S Yoruba Hymnary
OHUN ti n dun l'aginju, Ohun alore ni, Gbọ b'o ti n dun rara pe Ẹ ronupiwada! Ohun naa ko ha dun to? Ipe na ko kan ọ! Ki l'o se arakunrin, Ti o ko fi mira? Ijọba ku si dẹdẹ, Ijọba Ọlọrun, Awọn t'o ti fọ'sọ wọn, Nikan ni yoo gunwa; Ese t'o ko fi nani, Ohun alore yi, Ti dun l'eti rẹ tantan, Pe ronupiwada. Abana pẹlu Fapar, Le jẹ odo mimọ, Sugbọn asẹ 'wẹnumọ, Jordan nikan l'o ni, Ju ero rẹ s'apakan, Se asẹ Oluwa, Wa sun adagun yi, Wẹ k'o si di mimọ. Kin' iba da ọ duro? Awawi kan ko si, Wọ odo, wo Johanu rẹ, Ohun gbogbo setan; O pẹ ti o ti n jiyan, O ha bu Emi ku? Ẹlẹsẹ gbọ alore, Si ronupiwada. AMIN

Hymn 614 – OHUN ti n dun l'aginju | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia