Hymn 602 – EREDI irokeke yii | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EREDI irokeke yii" (C&S Hymn #602, Yoruba). EREDI irọkẹkẹ yii, Ti eniyan ti n wọ kọja? 'Jojumọ n'iwọjọpọ na, Eredi rẹ…

Hymn 602 – EREDI irokeke yii | C&S Yoruba Hymnary
EREDI irọkẹkẹ yii, Ti eniyan ti n wọ kọja? 'Jojumọ n'iwọjọpọ na, Eredi rẹ ti wọn n se bẹ? Wọn dahun lohun jẹjẹ pe, Jesu ti Nasaret' l'o n kọja Wọn dahun lohun jẹjẹ pe, Jesu ti Nasaret' l'o n kọja. Tani Jesu? Eese ti Oun Fi n mi gbogbo ilu bayi? Ajeji Ọlọgbọn ni bi, Ti gbogb' eniyan n tọ lẹhin? Wọn si tun dahun jẹjẹ pe, Jesu ti Nasaret' lo n kọja Wọn si dahun jẹjẹ pe, Jesu ti Nasaret' l'o n kọja. Jesu Oun na l'O ti kọja, Ọna irora wa layé; 'Bikibi t'O ba de, wọn n kọ Orisi arun wa 'dọ Rẹ; Afọju yọ b'o ti gbọ pe, Jesu ti Nasaret' lo n kọja. Afọju yọ b'o ti gbọ pe, Jesu ti Nasaret' lo n kọja Oun si tun de! Nibikibi, Ni awa si n ri 'pasẹ Rẹ; O n rekọja lojude wa O wọle lati ba wa gbe, Ko ha yẹ k'a f'ayọ ke pe? Jesu ti Nasaret' lo n kọja, Ko ha yẹ ka f'ayọ ke pe? Jesu ti Nasaret' lo n kọja Ha, ẹ wa ẹyin t'ọrun n wo! Gba 'dariji at'itunu; Ẹyin ti ẹ ti sako lọ, Pada, gba ore-ọfẹ Baba, Ẹyin t'a danwo abo mbẹ, Jesu ti Nasaret' l'o n kọja, Ẹyin t' a danwo abo mbẹ, Jesu ti Nasaret' l'o n kọja. Sugbọn b'iwọ kọ ipe yi, Ti o si gan ifẹ nla Rẹ, Oun yoo pẹhinda si ọ, Yoo si ko adura rẹ; O pẹ ju n'igbe na y'o jẹ: Jesu ti Nasaret' ti kọja O pẹ ju, n'igbe na y'o jẹ, Jesu ti Nasaret' ti ko. AMIN

Hymn 602 – EREDI irokeke yii | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia