Hymn 601 – Yo awon ti n segbe | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Yo awon ti n segbe" (C&S Hymn #601, Yoruba). YỌ awọn ti n segbe, Sajo ẹni n ku, F'anu ja awọn kuro ninu ẹsẹ, Kẹ f'awọn…

Hymn 601 – Yo awon ti n segbe | C&S Yoruba Hymnary
YỌ awọn ti n segbe, Sajo ẹni n ku, F'anu ja awọn kuro ninu ẹsẹ, Kẹ f'awọn ti n sina, gb' ẹni subu ro, Sọ fun wọn pe, Jesu le gba wọn la, Yọ, awọn ti n segbe, Sajo ẹni n ku lọ Alanu ni Jesu, yoo gbala. Bi wọn o tilẹ gan, Sibẹ, O n duro, Lati gb' ọmọ t'o ronupiwada Sa f'itara rọ wọn, si rọ wọn jẹjẹ, Oun o dariji, bi wọn je gbagbọ. Yọ, awọn ti n segbe, Sajo ẹni n ku lọ Alanu ni Jesu, yoo gbala. Yọ awọn ti n segbe, Isẹ tirẹ ni, Oluwa yoo f'agbara fun Ọ; Fi suru ro wọn pada s'ọna toro, Sọ f'asako p'Olugbala ti ku Yọ, awọn ti n segbe, Sajo ẹni n ku lọ Alanu ni Jesu, yoo gbala. AMIN Yọ, awọn ti n segbe, Sajo ẹni n ku lọ Alanu ni Jesu, yoo gbala.

Hymn 601 – Yo awon ti n segbe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia