Hymn 600 – EYIN eniyan Olorun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYIN eniyan Olorun" (C&S Hymn #600, Yoruba). ẸYIN eniyan Ọlọrun, Okunkun yi ayé ka; Sọ‘hin ayọ ti Jesu, Ni gbogb'…
ẸYIN eniyan Ọlọrun, Okunkun yi ayé ka; Sọ‘hin ayọ ti Jesu, Ni gbogb' orilẹ-ede, Ihin ayọ, Ihin ayọ, Ti 'toye Olugbala. Ma tiju ihinrere Rẹ, Agbara Ọlọrun ni, N' ilu t'a ko wasu Jesu, Kede 'dasilẹ f' onde, Idasilẹ, Idasilẹ , Bi t'awọn ọmọ Sion. B'ayé oun Esu dimọlu, S' isẹ Olugbala wa, Ja fun isẹ Rẹ, ma f'oya, Mase bẹru eniyan. Wọn nse lasan, wọn nse lasan, Isẹ Rẹ ko le bajẹ. 'Gbat' ewu nla ba de si yin, Jesu y'o dabobo yin; Larin ọta at' alejo, Jesu y'o je Ọrẹ yin; Itọju Rẹ, Itọju Rẹ, Y'o pẹlu yin tit' opin. AMIN
Hymn 600 – EYIN eniyan Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia