Hymn 596 – MA sise lo mase sole | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "MA sise lo mase sole" (C&S Hymn #596, Yoruba). MA sisẹ lọ mase sọlẹ, Ẹyin ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ikore pọ, ko s'agbase,…
MA sisẹ lọ mase sọlẹ, Ẹyin ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ikore pọ, ko s'agbase, Gbogbo wa ni yoo gb'ere na. Ma sisẹ lọ, mase sọlẹ, Ẹyin ọmọ Ẹgbẹ Kérúbù, Ẹ jade lọ s'opopo ayé, Gbogbo wa ni yoo gb'ere na. Ma sisẹ lọ, mase sọlẹ,, Ma jẹ ki fitila yin ku, Ọmọ 'ya wa ni ebi npa, Gbogbo wa ni yoo gb'ere na. Ma sisẹ lọ, mase sọlẹ, Awa ti de 'jebu-Ode, Ohun t'oju ri ko se sọ, Nigba t'a de onihoho. Ma sisẹ lọ, mase sọlẹ, Isẹ pọ n'ilu Ibadan; Abẹokuta ko ni sọ, Gbogbo wa ni y'o gb'ere na. Ma sisẹ lọ, mase sọlẹ, Ẹyin t'ẹ lo s'ilu oke, Ọpẹ f'Ọlọrun loke ọrun, Awa si tun ri ara wa. Ma sisẹ lọ, mase sọlẹ, K'a gb'ọwọ lọwọ ara wa, Ẹ ku abọ, Ẹyin ku 'le, Gbogbo wa ni y'o gb'ere na. Ma sisẹ lọ, mase sọlẹ, Mase wo awọn ẹlẹgan, K'a fi keta gbogbo silẹ, Gbogbo wa ni y'o gb'ere na. Ma sisẹ lọ, mase sọlẹ, Awa yoo kọrin Halleluya, Orin Halle, Halleluyah, Nigba t'a ba r'Olugbala, Amin, Amin, Asẹ. AMIN
Hymn 596 – MA sise lo mase sole | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia