Hymn 597 – JEHOVAH Rufi Baba wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JEHOVAH Rufi Baba wa" (C&S Hymn #597, Yoruba). JEHOVAH Rufi Baba wa, Fun wa l'okun ilera, Ki a le jọ f'iyin fun Baba,…
JEHOVAH Rufi Baba wa, Fun wa l'okun ilera, Ki a le jọ f'iyin fun Baba, Gẹgẹ bi awọn t'ọrun. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Gbogbo ayé, ẹ yin Jesu, Ohun rere d'ode, Ẹ fi iyin fun Baba l'oke, T'o d'Ẹgbẹ yi silẹ. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Gbogbo onigbagbọ Ijọ, Orun ododo d'ode, Ọlọrun n pe nisinsinyi, Ẹ jẹ k'a gbọ ipe Rẹ. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Jehovah Nissi Baba wa, Jẹ k'a le jẹ tirẹ, Ẹmi Mimọ 'Daba Ọrun, Jọwọ tọ wa s'ọna. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Ma banujẹ, ma b'ohun bọ, Ninu Ẹgbẹ Séráfù, Olupese, Olugbala, Ki yoo fi ọ silẹ. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Ẹyin Angeli mererin, T'e gbe ayé dani, Ẹ jọwọ ma f'ayé silẹ o, Ẹ ma wo 'wa ẹda. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Maikieli mimọ pẹlu ida Rẹ, N gẹsin fo yi wa ka, Kérúbù pẹlu ogun rẹ, La 'ju awọn ariran. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. A! ọjọ nla, ọjọ 'dajọ, Ma jẹk' oju ti wa, T'oju gbogbo ayé yoo pe, Lọdọ Baba l'oke A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Jesu masai ran wa lọwọ, Mase fi wa silẹ, Gbati 'danwo ba yi wa ka, Jesu gbe wa leke. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Ko s'ọrẹ t'o dabi Jesu, Ko s'ẹni mba ke pe, Mo wo 'waju mo wo ẹhin, Alabaro ko si. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Ranti pe o ti ko esu, Ati gbogbo isẹ rẹ, Egun ni fun ọ bi o tun Pada sọdọ Esu. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. Ogo ni fun Baba l'oke, Ogo ni f'Ọmọ Rẹ, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan lailai. A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu. AMIN A! ẹ wa k'a sin Jesu (2) Ipe na n dun, ronupiwada, A! ẹ wa k'a sin Jesu.
Hymn 597 – JEHOVAH Rufi Baba wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia