Hymn 595 – FUNRUGBIN lowuro | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "FUNRUGBIN lowuro" (C&S Hymn #595, Yoruba). FUNRUGBIN lowurọ, Ma sinmi tit' alẹ; F'ẹru oun 'yemeji silẹ, Ma fun sibi…

Hymn 595 – FUNRUGBIN lowuro | C&S Yoruba Hymnary
FUNRUGBIN lowurọ, Ma sinmi tit' alẹ; F'ẹru oun 'yemeji silẹ, Ma fun sibi gbogbo. 'Wọ ko mọ 'yi n hu, T'orọ tabi t'alẹ: Ore-ọfẹ yoo pa mọ, 'Bi t'o wu k'o bọ si. Yoo si hu jade, L'ẹwa tutu yoyo, Bẹni y'o si dagba soke, Y'o s'eso nikẹhin. 'Wọ k' y'o sisẹ lasan! Ojo, iri, orun, Yoo jumọ sisẹ pọ, Fun ikore ọrun. Njẹ nikẹhin ojo, Nigba t'opin ba de, Awọn Angel' y'o si wa ko, Ikore lọ sile. AMIN

Hymn 595 – FUNRUGBIN lowuro | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia