Hymn 594 – KO mi, Oluwa, bi a ti | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KO mi, Oluwa, bi a ti" (C&S Hymn #594, Yoruba). KỌ mi, Oluwa, bi a ti Jẹ gbohungbohun ọrọ Rẹ; B'O ti wa mi, jẹ k'emi…
KỌ mi, Oluwa, bi a ti Jẹ gbohungbohun ọrọ Rẹ; B'O ti wa mi, jẹ k'emi wa Awọn ọmọ Rẹ t'o ti nu. Tọ mi, Oluwa, ki n le tọ Awọn asako si ọna; Bọ mi, Oluwa, ki n le fi Manna Rẹ b'awọn t'ebi n pa. Fun mi l'agbara, fi ẹsẹ Mi mulẹ lori apata, Ki n le na ọwọ igbala, S'awọn t'o n ri sinu ẹsẹ. Kọ mi, Oluwa, ki n le fi, Ẹkọ rere Rẹ k'ẹlomi, F'iye f'ọrọ mi, k'o le fo De ikọkọ gbogbo ọkan. F'isinmi didun Rẹ fun mi, Ki n le mọ, b'o ti yẹ lati Fi pẹlẹpẹlẹ sọrọ Rẹ, Fun awọn ti arẹ ti mu. Jesu, fi ẹkun Rẹ kun mi, Fi kun mi ni ọpọlọpọ; Ki ero ati ọrọ mi, Kun fun ifẹ at'iyin Rẹ. Lo mi, Oluwa, an'emi, Bi o ti fẹ, nigbakugba, Titi em'o fi r'oju Rẹ, Ti n ó pin ninu ogo Rẹ. AMIN
Hymn 594 – KO mi, Oluwa, bi a ti | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia