Hymn 581 – E MA te siwaju, Serafu mimo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E MA te siwaju, Serafu mimo" (C&S Hymn #581, Yoruba). Ẹ MA tẹ siwaju, Séráfù mimọ, Gbe 'da sẹgun soke s'esu ati ẹsẹ,…

Hymn 581 – E MA te siwaju, Serafu mimo | C&S Yoruba Hymnary
Ẹ MA tẹ siwaju, Séráfù mimọ, Gbe 'da sẹgun soke s'esu ati ẹsẹ, Baba Olusẹgun ti sẹgun fun wa, Ẹ ma bẹru larin ainiye ọta, K'a se fẹ Oluwa, b'ara igbani, Oun to gbọ t'Abrahamu, Yoo gbọ tiwa. Ẹ ma tẹ siwaju, Kérúbù mimọ, Odi Jeriko wo nipa orin wọn, Lati ipa de'pa wọn n ko ikogun, Tẹsiwaju larin ainiye ẹgan. K'a se 'fẹ Oluwa, b'ara igbani, Oun to gbọ ti Mose, yoo gbọ tiwa. Ranti agbara Rẹ niwaju Ọba ni, Ranti isẹgun Rẹ ni okun pupa; Ọwọn Awọsanmọ ni ọsan gangan, Ati ọwọn ina Rẹ fun wọn l'oru, K'a se 'fẹ Oluwa, b'ara igbani, Oun to gbọ ti Joshua, yoo gbọ tiwa. Baba Olupese yoo pese fun wa, Ranti ipese Rẹ ninu aginju, Lati 'nu apata o fun wọn l'omi; O fi manna ati aparo bọ wọn, Ka se 'fẹ Oluwa b'ara igbani, Oun to gbọ ti Daniel, yoo gbọ tiwa. Ẹ ma tẹ siwaju, bi 'danwo ba de, Ẹ sa kun f'adura, ẹ o si bori, Agbara Oluwa ni abo fun wa, Ranti Sedrak, Mesaki at' Abednigo, Ka se 'fẹ Oluwa b'ara igbani, Oun to gbọ t'Elijah, yoo gbọ tiwa. Séráfù t'ayé yi, ẹ ku ajọdun, Kérúbù t'ayé yi, ẹ ku ajọdun; Ajọdun nla kan mbọ ti a o se loke, di Pẹlu awọn Mimọ lati yin Baba, Ka se 'fẹ Oluwa, b'ara igbani, Mẹtalọkan Mimọ yoo gbọ tiwa. AMIN

Hymn 581 – E MA te siwaju, Serafu mimo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia